Mo ki gbogbno awon ti won fi asiko won sile lati wa ka ohun ti a tun mu wa looni. Ohun ti a ma ko ara wa ni oni ni ABD olowe.
Kinni ama npe ni abd olowe.
Ohun ti abd olowe tumow si je kiko alifabeeti yoruba pelu owe.
Ni oni, a ma ko rawa lati ori A de E.
A: aigbofa la ma nwoke, ifa kan ko si ni paara.
para je nkan ti won ma nfi nse abo leyin ti a ba se orule ile tan ni aye atijo. Ohun ti owe yi tumo si ni wipe eni i o ba mo ifa re doju ami ko tun nilo lati ma wo oke mo. Wiwo oke tumo si wipe eni ohun fe fi asiko yen ranti ohun ti o fe so ni.
Ti a ba ko omode ni nkan, ti a wa bere ni owo re. Ti o ba bere si wo oke, o tumo si wipe ko fi okan si ohun ti a ko ni yen.
B: bibire kose fi owo ra
Bibire ni ile yoruba tumo si ki a fi asa, iwa ati ede ko omo wa lati kekere. Yoruba si gbagbo wipe ti a ba fi ohun ti o to ko omo lati kekere, eyi ni yio wu ni iwa titi yio fi di agbalagba.
Omo ti a ba kp ni akobaje, iru won ni o ma nse ipanle ati jagidijagan kiri ilu. Ika buruku ni awon eniyan yi o si ma tok si awon obi iru omo naa.
Omo ti a ba fi ohun irele and iwa ti o to ti o si ye ko nidakeji ewe, iru omo be ni yi o ko ogo ilu ati ile re jade.
Eyi tomo si wipe, bi eniyan se lowo to tabi ti o gbajumo to, iyen ko ni ki o fi owo ohun ra iwa rere.
Eyi inyen ti a fi ma npa lowe wipe bibire ko se fi owo ra; a ma nko ni.
D: dide dide la nba ile oyin
Oyin ke kokoro ti o ma nfo kaakiri inu oko. Oyin ma n fun wa ni ohun aladun ti a le ma lo fun jijie ati fun ilera ara.
Idi ti a fi ma nso wipe dide dide ni a ma nba ile oyin ni wipe, oyin ti fun adun inu re jade, eyi ti o san gbologb olo, ashan yi o ma nje ki ile oyin de jebe jebe.
Ohun ti o tun tumo si ni wipe, ko ye ki a ma mu nkan le kokoko. Ohun tutu ni ise ti o ma nse laye oto fun ibagnepo ti o dan moran.